Header Ads

ÌHÒÒHÒ OBÌNRIN

Ẹyin ilu ọmọ afagbọnja, ẹ ku ikalẹ, ẹ ku isinmi opin ọsẹ.
A maa nkorin kan pe:

Ko too gbemi sanlẹ, mo le gb’abẹ ẹ yọ
 
Ibẹrẹ l’ọmọde n r’oko ẹwẹ
Bi n o ba le mu ọ n’ija, ma si ge ọ jẹ,
Ara ija l’eyin ẹnu ọmọde

Abi bẹẹ kọ laa wi? Emi o tete mo wipe ara ija n’ihooho naa wa o, ẹ maa bami f’oye gbee bọ.

Awon akigbe nsere f’ọba l’aafin, ọba ns’ọjika, o njurukẹrẹ, o nwipe:
“Ọba ni mi, aṣẹ awon baba mi nbẹ l’ẹnu mi. Mo ba leri oso, mo ba leri ajẹ, mo ba leri ẹlẹbọloogun, ọba ba leri ohun gbogbo ni.”

Ohun Akigbe ja too, ilu ndun, orin nbọ:
(orin)
Pakute ọba mu j’eyin erin lọ
Pampẹ ọba mu j’eekanna ẹkun
Awon to ti mu l’atesin o ma bọ
Awon to ti mu l’atesin o le bọ ooo
Pakute ọba mu j’eyin erin lọọọọ……….

L’ojiji l’awọn obinrin ilu ya de biba. Awọn eeyan t’ẹyin naa mọ dunjudunju ni o. Abikẹ ọmọ iya elégbo to l’ọkọ n’ile Aro, Abẹo aláàádùn, Jitoni ile eleegun meje, Tunrayo olóbì n’ita olookan, Asani ẹlẹmu, Jọọsẹ ẹlẹkọ, Moriyeba isalẹ agbẹ, Mọradehun idi ose, awon baun baun naa ni o. Gbogbo won f’ọwọ mu iro asọ wọn gẹngẹ, oju kan bí ìbó.

Awon kan nwipe:
“Awa n’iya yin, awa l’aya yin, awa l’obiri aye.”
Bẹẹ l’awọn kan ninu won nkọrin wipe:
(orin)

Pẹki ayee ni pẹki ọrun
Oba Ojutiku ti pade ọlọjọ
Àfi pẹ̀ẹ́!

Pẹlu gbogbo bi ọba se nfọn taa ki won too de, nse lo d’agbada ẹ b’oju kia, to k’ẹhin s’awon obinrin ilu. Opẹlọpẹ iyalode, ọtun iyalode, iyaloja ati awon Olori l’aafin l’ara Kabiyesi to jẹ ki awọn obinrin yii tun asọ won ro mọ’dii.

Ẹyin agbalagba mo se iba yin o, ẹni ba beere ọrọ lo fẹ idi ẹẹ gbọ. Ẹnu omode t’ọmu ti nrun ni mo fi nbeere o, ẹyin ni ẹ bami f’eti agba gbọọ, ki ẹ si f’oye agba gbeeyẹwo, k’obi ọrọ yii t’ẹnu yin gbo ka ka ka. 

Kini itumọ nkan ti awon obinrin yi fẹẹ se?
Awon obinrin ti a nwi yii kii se oloogun tabi oloosa, won o si gbe nkan s’ara wa s’aafin, idi okowo ni gbogbo won ti nbọ. Kini won fẹẹ si han ọba alaye ti ọba o tii riri l’abẹ awon ayaba bi won se pọ to?
Bi won ba s’idi han ọba to pe ara ẹ ni ọkọ oso, ọkọ ajẹ, kini o sẹlẹ s’ọba?

Se ka wipe ọba - to le gb’ẹsẹ le obinrin to ba wuu l’aarin ilu- kò ‘ba’ lori ‘ihooho obinrin’ ilu ni?
Bawo lo se di eewọ f’oba lati r’ihooho awon obinrin ilu, to fi jẹpe awon atẹyintọ, ẹlẹkọ, oniru, elewe, ẹlẹmu, lo ko ọba alasẹ ekeji orisa l’aya jẹ, ẹni ti ko gboran s’awon ijoye l’ẹnu?

Bi kii baa se ọba nkọ, se bi awon obinrin ba s’ihooho han okunrin miran bẹẹ, boya ọga ile isẹ kan, tabi baale adugbo, tabi Ishola Amusulaya obinrin gunyan gan, se o l’ewu naa?
Njẹ iru ẹ ti sẹlẹ si ọba ilu kan ri n’ilẹ Yooba?
Ki lo sẹlẹ si ọba ọhun?

No comments