Header Ads

Àìsàn ọjọ́ ogbó

O ti pé ọdun meji bayi ti iya Kolajo ti ngbin kìn n’ilẹ. Aisan ọjọ́ ogbó ni wọn pe é tori iya yi ti lé l’ọmọ aadọrun ọdun. O ngba ounjẹ o sugbon ori ibusun to wa naa ni ntọ̀ ti nyagbẹ si. Awọn kan tiẹ ni ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ kan ti nsi mọ́lẹ̀.

Ninu iwadi ti Kolajo se, awon agba kan ni to ba sín iya yi ni gbẹrẹ kan ni atampako ẹsẹ̀ osi ko fi ebu da ẹjẹ rẹ, iya yi ó mi kanlẹ, wahala Kolajo ó d’ópin. Wọn ni ajẹsara ti iya ti jẹ ni igba ewe ni ko jẹ k’ẹmi rẹ o tete bọ́.

Àá péé gbọ́n ni o, a kii péé gọ̀. Eyin ti ẹ ni imọ̀ ẹsin, ẹyin agbaagba, ẹ gbọ́, sé kolapo o ni jebi esun ipaniyan to ba se bẹ́ẹ̀? 

Aanu iya ti nse t’ẹbi t’ọrẹ lori idubule to wa yi ti ko tiẹ le sọrọ, sé ki wọn fi silẹ bẹ́ẹ̀ ni? 

Sé o tọna ninu asa ati ẹsin ilẹ Yoruba ki a maa ran awon arugbo l’ọwọ lati ku? 

Njẹ ẹyin ti ri iru isẹlẹ bayi ri, kini won se si i t’ọrọ fi l’oju?

Ẹ ṣe
Odidere Ayekooto

No comments