Header Ads

ÌYÁ AGBA OLUDASILE ÌWÉ IROYIN AWIKONKO KÍ AYÉ PÉ OD'IGBA Ó ṢE* *Yoruba bọ wọ́n ní ẹ kú ìrójú ń gbẹyín ẹ kú ewu ọmọ. Bẹẹ naa ni ìwé mimọ sọ* *Ìyá àgbà Awikonko lójú ọl'̀rọ̀ tí fi ilẹ bora bí aṣọ, ìyá Agba tí lọ rá ìwo ẹṣin wá. Wọ́n ti dé ibusọ tí wọ́n, wọ́n ti sọ kalẹ nínú ọkọ̀ ayé yìí. Ó rí bẹ nítorí wípé gbogbo ìwé mimọ fi idi rẹ múlẹ̀ pé dandan ni ikú jẹ fún àwa ẹ̀dá asemi, adìẹ irana sì ni pẹ̀lú kí ṣe ohun a jẹ gbé . A ń bẹ adẹda, Aṣẹ̀dá pé kò fi ọdún kún ọdún, ìgbà kún ìgbà fún àwa tó kù láyé, ká tẹ ilẹ̀ yí pé, ká dúró ṣe ohun rere lórí òkè eepe, ká tẹ pẹpẹ, ká f'ọwọ́ pawu, ká ferigi jobi, ká fi ọ̀pá ṣe ìkẹta ẹsẹ̀ lọ́jọ́ ogbó bí ti ìyá Agba Awikonko ká tó lọ láyé* . *Fún ìdí èyí èmi Oludasile àti olùdarí ilé isẹ ìwé ìròyìn Odidere Ayekooto ń fi àsìkò yí báyin kẹ́dùn fún lílọ tí ìyá àgbà lọ ibi àgbà ń ré . Ó dá mi lójú pé ọkàn nínú àwọn ọmọ ọmọ ọmọ ìyá àgbà ni Awikonko ń ṣe. Ọba Èdùmàrè yio dúró tì gbogbo ẹyin ẹbi ti òkú ọrùn fi silẹ lọ*. *Ní orúkọ Èmi àti àwọn ìdílé mi Alhaji Saliu Oyewole-Erinle àti ìyáàfin Ọtún iyalode Hon Faridat Taye Oyewole-Erinle báyin kẹ́dùn, àtún ń fi àdúrà dúró tì yín ṣinṣin ni àsìkò ìdárò ipapoda tí ìyá àgbà tí ẹ wà yi àti kárí gbogbo ẹbí yín lápapò pé ẹ kú idele ìyá onínú ire tí ó ré ìwàlàaṣà* *A wá ń fi àsìkò yí bẹ adẹda fún gbogbo àwa ti a n bá Awikonko daro tí ìyá wọn àgbà pé kí elédùmarè ó jẹ ki ọdún ó jìnnà sì ara wọn fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa*.àmín *Awikonko ọmọ l'oku, a baja ni ọrùn, Ọlọ́run a bò yín ní àṣírí*. *Ẹ má gbàgbé láti fi ìwé ìpè ransẹ sì gbogbo àwa olólùfẹ́ yin nígbà tí ẹ bá ń ṣe ẹyẹ ìkẹyìn fún ìyá àgbà*. *Ẹ ṣe* *Ọmọ rere a gbeyin àwa náà bí ti ìyá àgbà Awikonko lójú ọ l'ọ̀rọ̀ , kọ l'ọ̀rọ̀ ó gbọ*

July 10, 2018
ÌYÁ AGBA OLUDASILE ÌWÉ IROYIN AWIKONKO KÍ AYÉ PÉ OD'IGBA Ó ṢE Yoruba bọ wọ́n ní ẹ kú ìrójú ń  gbẹyín ẹ kú ewu ọmọ. Bẹẹ naa ni ìwé mimọ...Read More