Header Ads

DÍẸ̀ NÍNÚ ÀWỌN ỌMỌ ẸGBẸ́ ỌLỌ́WỌ́ APC POHÙN DÁ BỌ AṢỌ ÌPÌN ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ APC SILẸ NÍ ILE IGBIMO ASOJU SOFIN












Ọwọ̀ kọ, kò f'ẹnu kò laarin awọn ọmọ ẹgbẹ́ Ọlọ́wọ̀ APC ní ilé ìgbìmò asofin àgbà àti kékeré ni Olú ìlú wá Abuja.
Àkàrà Dórí Akayin Ó D'egun ni ọ̀rọ̀ ̀ yíyọṣẹ bí ẹni yọ jiga tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ apc niyọsẹ ni kété tí alàgbà Adams bọ si orí Ipò Alága Ègbé Ọlọ́wọ̀ APC .
Diẹ nínú àwọn ọmọ  ẹgbẹ́ olówò Darapọ mọ ẹgbẹ́ alanburela ìyẹn PDP ni ile Ìgbìmò asofin Àgbà Àti asofin Kékeré lónìí òde ọjọ́ isegun ọjọ́ kẹrìnle logun oṣù okudu tí ọdún tí a Wàyí yìí.
Àgbájọ ọwọ ni àwọn àgbà ní a fi nsọ àyà, wọ́n ní òṣùṣù ọwọ́ ni gba'lẹ ̀  mọ, ọ̀rọ̀ kò rí bẹ fún àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ọlọ́wọ̀ ìyẹn APC ni ile ìgbìmò aṣojú sofin àgbà àti kékeré nínú gbọnga ìpàdé lónìí tí ṣe ọjọ́ kẹrinlèlógún nínú osù okudu tí ọdún yìí níbi tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ọlọ́wọ̀ apc f'ariga, fi ìbínú dá ọwọ̀  ọwọ́ wọ́n sílè tí wọ́n fi ẹgbẹ́ alanburoda PDP ṣe òpin ìrìn àjò nínú akitiyan isẹ òṣèlú tí wọn yàn laayo .
Àjálù ńlá lo de ba ẹgbẹ́ APC pápá julọ olórí ẹgbẹ́ náà tuntun ìyẹn Adams Oshiomole tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ bọ sì orí apere alága ẹgbẹ́ olówò APC ni ìkan bí oṣù kan sẹ́yìn. Se ká wá sọ pé ẹsẹ̀ bàbá yí o dára ní nínú ẹgbẹ́ náà ni.
Eyi to báni lọ́kàn jẹ julọ ni wípé àwọn ẹgbẹ́ olówò APC tí wá di olórí ẹgbẹ́ alátakò nínú ilé ìgbìmò asoju sofin àgbà báyìí, kí Ọlọ́run má jẹ́ kí a rí apada si laburu.
Gbogbo akitiyan àti ìlàkàkà  ìjọba àpapọ̀ àti àwọn agbofinro orile wá Naijiria kí ìjókòó àwọn ọmọ ile ìgbìmò asoju sofin àgbà  má  wáyé lónìí lo ja si pàbó, tí okete sì bórù mọ gbogbo wọn lọ́wọ́, ọgbọ́n inú tí ejò fi ń gùn àgbon ni ọmọ Bukola Sàràkí lo fi tà gbogbo wọn yọ, afẹri ni bàbá lo de ile ìgbìmò .
Àwọn ọmọ asoju sofin àgbà márùn-ún dín lógún ni wọ́n kéde pé ilẹ̀ gbigba pẹlu ọwọ lọ́wọ́ àwọn tí di ẹrú tí àwọn ko le gbe mọ, pé o ti sún àwọn, ti wọn si ti pinnu pé ẹgbẹ́ olonburela PDP lo lè gbà àwọn nígbà òjò wẹ́liwẹli.
Ni bayii, awon ṣẹnatọ tí ẹgbẹ́ òṣèlú olówò APC tí joró ni ile ìgbìmò asoju sofin ku merinlelogoji, ti àwọn ọmọ ẹgbẹ́ alanburela PDP tí gbénu sókè bayi tí di mẹrinlèlọgota, tí ẹgbẹ́ alakukọ APGA  ni   ẹyọ ọmọ ẹgbẹ́ kan.
Nínú ìròyìn tí ó tún tẹ wá lọ́wọ́ ilé ìwé ìròyìn Odidere Ayekooto  ni pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ọlọ́wọ̀ apc mẹtalelọgbọn lo tun tí darapọ mọ ẹgbẹ́ alanburela PDP, tí merin sì darapọ mọ ẹgbẹ́ ADC lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.

No comments