Header Ads

ÈRÈ ÀÌGBỌRÀN

Abikẹ nwa ẹkun mu l’oru ọjọ kan ni baba arugbo kan ba de.
“Ẹ kaabọ baba, mo ti ngburo yin tipẹ, inu mi dun lati gba yin l’alejo. Baale mi o si waa si n’ile bayii...”
“Abikẹ, eese ọ t’ẹkun at’ikoro kun ile aye ẹ bayi?”

“Baba, nitoripe ayọ ati adun ti dagbere ni o. Odun keje ree ti a se igbeyawo, mi o l’oyun aarọ d’alẹ. O d’ọsẹ meji bayii ti baale mi ti sunle gbẹyin, iyakọ mi o si jẹ nr’imu mi n’ile.”

“Ma l’aagun jinna, gbogbo b’ọrọ ile aye ẹ se ri ni mo mọ. Njẹ o ranti ikilọ ti mo se fun ọ koo too se igbeyawo?”

Abikẹ ronu lọ fun igba diẹ, o ni “Mo ranti baba”
“Njẹ o tele ikilọ naa bi?”

Abikẹ tun bu s’ẹkun. 

Ọrọ ti Abikẹ ranti sẹlẹ ni asiko ti wọn sẹsẹ dajọ igbeyawo. Adari ile ijọsin gba Abikẹ n’imọran pe ko ma se igbeyawo alariwo, paapaa ni ilu won. Bi Abikẹ i ba se fẹ lati tẹle ikilọ yi to, iya Abikẹ f’aake kori. 

“Iru palapala wo niyen, Olọrun majẹ ki won o gbemi pamọ l’ọjọ ẹyẹ mi. Mo se f’alara, mo se f’ajero, ki temi waa de, ki nd’ọwọ boo, ka ma rii. Tete lọọ wi fun awon olosi ti won nririkurii si ọ wipe oju asa kii r’ibi.” 

Wọn se igbeyawo yii ni Lalupon, aye gbọ, ọrun mọ, pẹpẹyẹ pọnmọ o gbajaa.

Baba tun fọ hun; “Se ọrọ ekun nii kan bayi, Abikẹ? Igbọran o wa san ju ebọ riru lọ?” O f’ọwọ bọ Abikẹ l’oju. “Iwọ naa wo ohun to sele l’ọjọ igbeyawo ẹ…..”

Ọmọdebinrin kan gbe onjẹ wa s’ile iya ọlọka. 

“O seun ọmọ. Gbee s’ori tabili nbẹun.”
Ọmọ lọ ni, iya si awo onjẹ, o kọ ha! 

“Egbin oniyọrọ. Se emi waa jẹ bii arobo ni won se fi ẹran rodorodo meji le ori iresi fun mi. E r’aye l’ode bi o.?”
Iya koju si koro yaara, o patewo po po po l’eemeta, o ni;
“Ẹyin iya mi ọrẹrin ija k’ọmọ l’oju, ẹ gbami o, ẹyin yerepe ọran tii ku l’ori alaigbọran, ẹ dakun ẹ yami ni akẹyinjẹ, mo fẹẹ ran n’isẹ kan ni werewere. Akẹyinjẹ oooo!” 

Afi gija ti ẹmikẹmi kan bẹ silẹ lati ara ogiri ile, o bani l’ẹru gidi. 

“Kaabọ, akẹyinjẹ, tara sasa bayii koo ree ba Abikẹ ọmọ Asake ati Akanmu ọmọ Jeigbe rin irinajo igbeyawo wọn. Ooo gbọdọ j’iyan, oo gbọdọ j’ọka n’ile won, sugbon gbogbo ẹyin takọtabo won ni koo maa jẹ. O ya, ọjọ ti bomubomu ba wale aye, ọjọ naa ni soponna nboo, oojọ l’oro itọ ọ mulẹ, kankan l’ewe ina jo’mọ.” 

Bafo ni ẹmi yii poora.
Abikẹ tara giri, o w’oju baba arugbo.

“Iwọ naa rii bayi Abikẹ, aigboran lo la ogiri igbeyawo rẹ l’ẹnu, ti alangba esu fi rapala wọọ. Waa gbera bayii, at’iwọ ati baale rẹ, ki ẹ wa Adari ijọ yin lọ, gbogbo bi ẹ o se ja ogun naa ni ajasẹgun, iransẹ mi o maa s’alaye fun ọ.”

Wai ni Abikẹ la oju, ase ala lo nla. 

Ni asiko yii kannaa, ni ilu kannaa n’ibi ti Akanmu ti lọọ s’aba ti alagbere obinrin kan, baba arugbo yii kannaa lo sọ fun wipe; “Akanmu, oju ọna iparun lo wa. Afira bai, tete lọọ ba iyawo rẹ n’ile, o ti ri asiri ogun ti nja igbeyawo yin.” 

Oru yii naa ni Akanmu pada s’ile. Nse ni tọkọtaya won tun bẹ s’ita bi ẹni ejo kamọ iyẹwu, o di ile ijọsin. Bi ofeere ti nla l’ọjọ keji ni won ti tẹ ọkọ l’eti, o di Lalupọn.

N’iwaju ile iya ọlọka, tokotaya gb’ẹru kalẹ, won dobalẹ tii, won nbẹ iya.

“Maami, ẹ dakun, ẹ darijin wa. E woo, mo ti se onje aladun wa, koda mo tun ra orisirisi ẹbun iyebiye sii.” 

Akanmu si awo onjẹ han iya; ẹdọki, ọdofolo nni saki l’ara, igbin nyaju si bọkọtọọ, ogufe nse igberaga si panla, bẹẹni pọnmọ ka wereke mọ ahọn ẹran bi ololufẹ meji.

Oju iya yo sando. “Abikẹ taa lo kọ ọ l’eyi too se yii?”

Iransẹ Oluwa ni; “Alaafia fun yin mama”

Iya wo alagba yii roro, o ni “Abajọ, mo wi bẹẹ naa.” 

Oju iya walẹ diẹ. 

“Woo, Abikẹ, mo binu si ọ pupọ, sugbon inu mi ti yọ si ọ bayii, aa s’atunse si gbogbo nkan to ti bajẹ. E duro demi.” 

Iya wole lọ, o gbe awo ọlọmọri kan jade. “Awo onje yin ọhun ree o, njẹ ko ti p’ọdun meje? Iwọ ọkọ iyawo gba, sii wo.” 

Akanmu gba awo l’ọwọ iya, o sii. Aye toto o. Njẹ ẹ mọ wipe bi onjẹ naa se ri lati ọdun meje s’ẹhin naa lo tun ri, ko bu, ko kan, ko tutu, afi bii k’eeyan tun maa jẹẹ.

Iya rẹrin, o ni: “O nya yin l’ẹnu pe onjẹ naa si wa bo se wa abi, ẹẹn o, ẹjọ laa b’oogun ro, b’ọmọde o ba m’ẹwẹ l’ẹwẹ, ti o m’owe l’owe, se laa j’ẹwẹ s’ọwọ ọtun, aa si j’owe s’ọwọ osi, aa fi han an. E gbee bayi wọ inu igbo lọ, ki ẹ bo onjẹ naa mọlẹ, ki ẹ si fọ awo, ni ide agan ile aye yin ba tu.”
Bi tọkọtaya se gb’onjẹ wọ’gbo lọ ni iya tun kọju si origun ile, o patẹwọ l’ẹẹmẹta, o tun ni;
“Akẹyinjẹ o! Boo wa n’itọ-aja, too wa n’idọrọmi iwasẹ, o ya maa bọ bayi, ile koko ni t’agbe. Isẹ eleyii ti pari, waa sinmi na titi ti aa fi tun r’alaigbọran miin.”
Ẹmikemi ijọsi pada de, o wọ inu ogiri ile lọ. 

Abọde Lalupon, Abikẹ o m’osu naa jẹ o, afọn gbo, afọn wọ, a gb’ohun iya, a gb’hun ọmọ, ojojo kan o si se baba ọmọ. 

Ẹ o wa rii pe Olorun ni nbẹ l’ẹyin ajekuru, Alahurabi ni nbẹ l’ẹyin ajewasun, amọ bi igi, bii kumọ ni nbẹ l’ẹyin alagidi, alaigbọran, to wipe ẹnu agba nrun. Irin o t’inu igbo p’ẹja l’omi o, bẹẹni, igere o t’inu odo m’odu ọya, aigbọran o l’ere. 

Bi iwo ba waa ri aye, ke pe Olodumare Ajagunsegun wipe:
Oluwa o, fi aanu tu asiri ogun ti njami l'oni o.

No comments