Header Ads

IMISI ÈDÙMÀRÈ

ÌWÉ JEREMIAH ORÍ KẸRINLELOGUN ẸSẸ KẸFÀ

òjò kú gìrìrìrì! ọlá ROTIMI Àbíkẹ́yìn Ajigbọtibaale yọjú l'ójú fèrèsé n'ílé isẹ tó ti ns'isẹ iwakusa epo robi gẹ́gẹ́ bí alamojuto isuna owo l'Eko aromisa lẹgbẹ, ó nka ìwé ìròyìn l'ọ́jọ́ yìí ló bá rí olobó wípé ààyè ipò kan tó gbé pẹẹli sí silẹ ninu ètò ipò oṣèlú lorile-ede Naijiria ni ilé ìgbìmò asoju sofin ni Olú ìlú Abuja.

"Aaaga, dídùn l'ọsan yi so, àfi bí mo kaa".

ọlaROTIMI gbé gege lé takanda, o sọ pónpó s'ọsan, ọwọ dẹ, ọsan wọ.
Gẹ́gẹ́bí òfin ilé isẹ, ọláROTIMI tá ọga ẹ l'olobo láti fún ilé isẹ ni gbedeke ọ̀sẹ̀ méjì àti láti ṣe ipalẹmọ to yẹ. Afi bíi pé ọga ọlaROTIMI tí ńdúró dee tẹ́lẹ̀ ni, kò too pé ọgbọ́n ìṣẹ́jú, wọ́n ti fún AYỌNI to jẹ́ igbakeji ọláROTIMI ni ìwé láti bọ s'órí ipò tí ROTIMI wá.

Ìwé tí ọga fún ROTIMI ká báyìí wípé :
"ROTIMI Àbíkẹ́yìn , l'órúkọ àwọn aláṣẹ ilé isẹ yìí, mo bá ọ yọ fún tí ìṣẹ yìí, mo bá ọ yọ fún tí isẹ tuntun, mo gbà ọ l'áyé kí ó wà pẹ̀lú wa fún oṣù kan, ṣùgbọ́n ó níláti kò gbogbo ohun ìní ilé isẹ tó wà n'ikawọ àti àmójútó rẹ fún Abilekọ Ayọni Orijajogun ni warasesa.

Inú mi yoo dùn bí ó bá lè pá gbogbo òfin ilé isẹ yìí mọ títí tí oṣù kan tí a fún ọ ó fi parí"

Inu ọláROTIMI bàjé nítorí ìwà ọga yìí bàa n'ijafuu, kódà Ayọni náà tí bẹ̀rẹ̀ gaaru. Ọjọ́ yìí náà ni àtẹjisẹ ibanujẹ, kobetirẹ kan tún wọ orí aago ilewọ rẹ.

" ìyáàfin olaRotimi Àbíkẹ́yìn ó ndunmi láti fi àsìkò yìí wí fún yín pé a ó níí lè gbà yín sisẹ n'ílé ìgbìmò Orísumbare l'ásìkò yìí nítorí àwọn aláṣẹ ilé isẹ wá ti luu ni gbanjo. Ẹ fiyèdénú bí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí bá ko ìdààmú bá yín, kii se àfínnúfíndọ̀ṣe".
Ẹ ó wà ríi pé ibi ọsan wọ sì f'Abikẹ ROTIMI ha gadigadi, kò see sá?. Àbíkẹ́yìn ROTIMI tí dá omi agbada nù, ojo kọ, ojo ó rọ, ó kú atiromiwẹ
.
Kíá l'Abikẹ sáré tete rèé bá ọga:,
"Ọga ẹ gbami, ẹ pami s'ile, ẹ má pami s'ita".

Ọga rẹrìn iyangi, ó ní, Abikẹẹẹẹ! Ìwọ náà mọ wípé mo fẹ́ràn  igbajumọṣẹ rẹ, botilẹjẹpe nigbati ojo npami, ó dájú mi, oo gbami s'ile, ọkọ ẹ lo gbajumọ, ó ti gbàgbé wípé gbogbo eeyi t'ojo ṣe, ẹẹrun ń bọ̀ waa bèèrè. Òfin ilé isẹ ó gbami l'áàyè láti gba ìwọ naa n'ígbà t'ẹẹrun mú ọ yìí. Jáde lọọfiisi mi, mo n'isẹ ẹ ṣe".

Abikẹ tún lọọ bá Ayọni . Ayọni gbamiii, gbogbo èyí tó ṣẹlẹ̀ yìí sí l'atunse boo bá fẹẹ ranmi l'ọ́wọ́, ó sì mọ p'emi náà o jẹ bẹẹ, ó sẹ ṣ'ápá l'oni ni ó, ó le ṣẹ s' itan l'ọla".

Ayọni nyí l'órí àga ipò ọga tuntun tó wà ó y'ẹnu gẹrẹ. Ẹ woo, misiisi patanmọ, èmi kọ ní mo koba yín , ab'omi òkun at'ọsa l'emi wáa wo l'Eko ni?. Kuo níwájú mi síọ,oniranun.

Dabimoseda agb'ọkọ lérí pantete, ọlọkunrin to fẹẹ f'omitooro ejò jẹ'rẹsi".
Ọna d'orí àpáta ó pín f'Abikẹ . Níbo laa bá yaara ja?

ọláROTIMI délé l'alẹ, ọjọ́ náà, ó f' ẹ́jọ sún Bàbá Eletiigbaroye.

"Èéṣe tí ó gb'áwọn ọ̀tá l'áàyè láti fimi ṣ'ẹ̀sín bayi, olúwa mi? Ìlérí igbega tí ó ṣe Funmi n'ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yìí dá bayi?".

Ọ̀run dakẹ rọrọ bí ẹni tí ó leè rọ'jo, àmọ́ Eletiọfẹ gbọ́, ọba tí gb'àdúrà rán imisi.

olaROTIMI nù ojú nù. Ó ń fọkàn ro imisi Adániwáyé. Ó di ọ̀rọ̀ náà mú ṣinṣin, ó ńjẹẹ l'ẹ́nu, ó ṣáṣáro l'ori ẹ tọsantoru títí tí oṣù kan tí wọ́n fún un n'íbi isẹ fi pe. Ó retiremu, ọga ó yí ẹnu padà ó, Abikẹ ó r'osan, kò rí pónpó, kò r'omira, kò r'ẹjẹ, ọmọ ọrùn ó w'áyé.

Aago márùn-ún lu l'ọ́jọ́ tó kẹ́yìn oṣù, a kii s'ọrẹ èrò ká yo, onílé a relé. Ó dagbere fún gbogbo àwọn alabasisẹ, isẹ tán, ìpàdé wá bí oyin.

Aago ọláROTIMI dùn. Ó dá ọlọkada dúró kò lè dáhùn ìpè.

"Abilekọ Ajigbotibaale ọláROTIMI njẹ ẹ sì wá nínú ọgbà ilé isẹ? Ìyàlẹ́nu lo jẹ láti gb'ohun ọga pátápátá. Bẹẹni sá. Kini mo lè ṣe fún yín sá?"

Ọga gbẹkọ kẹhẹ. Ọga àgbà to ns'akoso ètò isuna owó tí fi isẹ silẹ lojiji, àwọn ètò ọrọ aje tuntun tí ilé isẹ wá fẹẹ gbé kaná láti ọ̀la lọ nwa àbójútó kíákíá, ẹyin lẹ kúnjú Osunwọn tí ẹ wà nítòsí, njẹ ẹ n'ifẹ sì ipò yìí"?.

olaROTIMI f'ọwọ́ bójú, ó ní 'irú àlá amunironu wo l'eyii?

"Mo fẹ́ kí ẹ bẹ̀rẹ̀ isẹ l' aarọ ọlá, ìwé igbanisisẹ yín tí wá l'ọdọ akọ̀wé mi. Ẹ kú oriire ó"?
Abikẹ wàá nwi kantankantan. "Ẹ seepọ sá, a dupe sá, yóò kó- nii d - ah- sórí sá, yóò dáa fún yín sá",
Ọga tí pá aago ńtiẹ̀, kò gbọ mọ.

Hmmmnń, kí wàá ni ọga kékeré àti Ayọni ó ṣe bo ba d'ọla?

Ẹ Kú ìkàlẹ, ẹyin olólùfẹ́ Odidere Ayekooto.

Ẹ wípé imisi wo ni ọlaROTIMI gbọ l'órí àdúrà ọjọ́sí?
" Èmi ó kọjú mi sì ọ fún rere, èmi ó mú ọ padà wá s'ile yìí, èmi ó gbin ọ, èmi ó níí fà ọ tú."(ìwé Jeremáyà orí kẹrinlelogun, ẹsẹ kẹfà).

Mo dúpẹ́ fún àsìkò yín tẹ fi silẹ gbádùn àyọkà mi yìí. Ó dá bí eré ọmọdé ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ inú rẹ ni mo fẹ́ ká di mú. Yoruba bọ wọ́n ní A pọnmi tá kí pofo, kí sì pá dànù, ẹni tó gb'ọkan le Oluwa kí jogun òfo. Ìdúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ ẹni ó ṣe kókó, ó ṣe pàtàkì, ohun níkàn sì ni ọ̀nà àbáyọ gbogbo ore wá kò ní fowaru láṣẹ Edumare.

O digbakan naa, o tún d'ọ́jọ́ rọ
Odidere Ayekooto loni ire o
Odidere Ayekooto

No comments