Header Ads

AWON EEWO ILE YORUBA

Eewo je okan lara asa ti awon Yoruba ko fowo yepere mu rara paapaa laye atijo. Awon Yoruba a maa lo eewo lati dena ijamba, rogbodiyan, iyonu, ati bee bee lo.

Eewo wa fun ikora-eni-ni –ijanu,o wa fun ikonilogbon ninu irin ajo eda lori ohunkohun lori ile aye.Eewo ile Yoruba pin si isori isori bii eewo idile, eewo ilu, eewo esin, eewo,imototo,
eewo aisan ati bee bee lo.

Idile kookan lo ni eewo tire ni ile Yoruba yato si eewo lapapo gege bi omo kaaro o-o jiire. Eyi ni nnkan aigbedo ti enikeni ko gbodo se tabi danwo ninu ebi naa. Iru eewo bayii a maa saaba ba awon iyawo ile wi nipa ibimo, itomo, iwomo bi apeere ni idile ayan(idile onilu) ti won ba sese bi omo tuntun won gbodo toro gbogbo ohun elo ti won yoo fi we omo tuntun naa fun igba akoko, ti won ko ba se bee omo naa yoo maa tiju ise idile re,ko ni lee se e tabi fi yangan.

Iran onikoyi ko gbodo eran okete , itan fi yeni pe baba nla won binu di okete laye ojoun , iran ikoyi to ba je okete baba nla re lo je gege bi igbagbo awon Yoruba.

Idile olu oje ko gbodo je eye ega, nitori awon eye ega wonyii lo ran baba nla won lowo laye ojoun gege bi itan se se so lati segun awon ota won.

Iran Orile Alapa kii je ejo, itan fi ye nipe baba nla won di ojola, o si wo wonu odo laye atijo, nitori naa iran Alapa ti o ba je ejo baba nla re lo je.

Awon idile kan wa ni ile Yoruba to je wipe ti won ba bimo, iya omo ko gbodo je obe ti o ni iyo, obe ate ni o gbodo maa je titi di ojo isomoloruko,idile miiran obe ofun , iyen obe ti a ko fi epo pupa se, idile miiran eran alangba ni won maa fi se obe fun un, obinrin ti o ba déjà yii omo re yoo ku tabi ki
aburu miiran sele sii lojo iwaju.

Esin kookan lo ni awon eewo ti awon olusin won ko gbodo se rara ti won ko ba fe ri ija orisa naa, bi apeere; awon olorisa nla ko gbodo mu emu, won ko gbodo je eran eleje, won ko gbodo fi epo-pupa se obe ayafi ori, won ko gbodo lo nnkan to ni awo pupa nitori won gbagbo wipe orisa mimo ni orisa yii.

Eewo ni ki olorisa okunrin joko sori apoti ti iyawo olorisa egbe re fi jokoo.

Obinrin ti o ba n se nnkan osu re lowo ko gbodo de ojubo orisa.

Eewo ile Yoruba lapapo Eewo ni ni ile Yoruba egbon ko gbodo jogun aburo re, bee naa ni baba ko gbodo jogun omo re.

Omo ko gbodo jabo leyin iya re, yala omo okunrin tabi obinrin, ti eyi ba sele ti omo naa ba je okunrin iyawo mesan an ni yoo ku mo-on lori, ti o ba je obinrin oko meje ni yoo ku mo-on lori.

Alaboyun ko gbodo rin losan gangan nigba ti oorun ba kanri, tabi ki o lo pon omi lodo, awon Yoruba ni igbagbo pe asiko yii ni awon emi airi/abami maa n ri kiri won si le ko wonu alaboyun yii laimo.

Eewo ni ki enikeni o maa sufe (whistling)lale , o maa n pe ejo wole.

Oba ko gbodo ri inu ade ti o wa lori re eewo ni.

Egbon owu ti a fi ko idoti eti ko gbodo deoju ara eewo ni ni ile Yoruba.

Ti okete ba ti ko owo mejeeeji soke, ti o fie se tiro, enikeni ko gbodo paa, eni ti o ba déjà eewo yii , ti o ba bimo ti o ba to asiko ti awon omo re ba fe maa gbiyanju lati maa rin ni omo naa yoo ku.

Eewo ni ni ile Yoruba won ko gbodo sin oku eni ti o ku soso si ile, eti odo ti o ku si ni won gbodo sin in si.

Eewo ni won ko gbodo sin oku eni ti o jabo lori igi tabi ope si ile, ti won ba déjà akufa ni yoo je fun iru ebi bee.

Odidẹrẹ Ayekooto

4 comments:

  1. Dub t and MUMY tomorrow perf lekki phase me to y out covered in the morning as arranged for a while MA wanted to say hello to him and her that

    ReplyDelete
    Replies
    1. Ddfgvdd for me to help sell avon. I have a wonderful week ahead of you and family doing today and family and business going sure great thanks to God Dcgf for her to enter this card is a new fragrance is it going u want to be sure I will have to go there now unilag education complex and I don't want to talk too much or stay too long to get a chance to win the lottery ticket for the likes and follow me please I need this for my business and I don't want to talk too much or stay too long to

      Delete